9‘Èmi mọ́, láìní ìrékọjá, aláìṣẹ̀ ní èmi; bẹ́ẹ̀ àìṣedéédéé kò sí ní ọwọ́ mi.
10Kíyèsi i, Ọlọ́run ti rí àìṣedéédéé pẹ̀lú mi; ó kà mí sì ọ̀tá rẹ̀.
11Ó kan ẹ̀ṣẹ̀ mi sínú àbà; o kíyèsi ipa ọ̀nà mi gbogbo.’
12“Kíyèsi i, nínú èyí ìwọ ṣìnà! Èmi ó dá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ!
13Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń bá a jà, wí pé, òun kò ní sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀?