Jobu 33

Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀.

Job 33:14 (UKJV) For God speaks once, yea twice, yet man perceives it not.

12“Kíyèsi i, nínú èyí ìwọ ṣìnà! Èmi ó dá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ!

13Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń bá a jà, wí pé, òun kò ní sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀?

14Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀.

15Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ibùsùn,

16nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.