13Ní ìrò inú lójú ìran òru, nígbà tí oorun èjìká kùn ènìyàn.
14Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrì tí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé.
15Nígbà náà ni ẹ̀mí kan kọjá lọ ní iwájú mi, irun ara mi dìde dúró ṣánṣán.
16Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀, àwòrán kan hàn níwájú mi, ìdákẹ́rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé,
17‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run, ènìyàn ha le mọ́ ju ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí?