5Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọlù ọ́; ara rẹ kò lélẹ̀.
6Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?
7“Èmi bẹ̀ ọ́ rántí, ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀? Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí?
8Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.
9Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé, nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun.