20Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e; wọ́n dé bẹ̀, wọ́n sì dààmú.
21Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn; ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.
22Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá, tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?
23Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni, tàbí, ẹ rà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì’?
24“Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́ kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti ṣìnà.