31síbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.
32“Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi, tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.
33Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.
34Kí ẹnìkan sá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi, kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì ṣe dáyà fò mí.
35Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀; ṣùgbọ́n bí ó tí dúró tì mí, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.