22Ààlà náà sì dé Tabori, Ṣahasuma, àti Beti-Ṣemeṣi, ó sì pin ní Jordani. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rìndínlógún àti ìletò wọn.
23Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Isakari, ní agbo ilé agbo ilé.
24Kèké karùn-ún jáde fún ẹ̀yà Aṣeri, ní agbo ilé agbo ilé.
25Lára ilẹ̀ wọn ni èyí: Helikati, Hali, Beteni, Akṣafu,
26Allameleki, Amadi, àti Miṣali. Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ààlà náà dé Karmeli àti Ṣihori-Libinati.