Ẹkún Jeremiah 3

Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi.

Lamentations 3:15 (UKJV) He has filled me with bitterness, he has made me drunken with wormwood.

13Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.

14Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.

15Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi.

16Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.

17Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.