6Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.
7Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.
8Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi.
9Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.
10Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.