24“Bí iná bá jó ẹnìkan tí àmì funfun àti pupa sì yọ jáde lójú egbò iná náà.
25Kí àlùfáà yẹ ojú ibẹ̀ wò. Bí irun ibẹ̀ bá ti di funfun tí ó sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lásán lọ, ààrùn tí ń ràn ká ti wọ ojú iná náà, kí àlùfáà pè é ní aláìmọ́. Ààrùn tí ń ràn ni ni èyí.
26Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí kò sí irun funfun lójú egbò náà tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí ó sì ti gbẹ, kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.
27Kí àlùfáà yẹ ẹni náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ń ràn ká àwọ̀ ara, kí àlùfáà kí ó pè é ní aláìmọ́. Ààrùn ara tí ń ràn ni èyí.
28Ṣùgbọ́n bí ojú iná náà kò bá yípadà tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara. Ṣùgbọ́n tí ó gbẹ, ìwú lásán ni èyí láti ojú iná náà; kí àlùfáà pè é ní mímọ́. Ojú àpá iná lásán ni.