Lefitiku 13

Bí ààrùn náà bá ṣe bí ọbẹdo tàbí bi pupa lára aṣọ, ìbá à ṣe awọ, ìbá à ṣe ní ti aṣọ títa, ìbá à ṣe ní ti aṣọ híhun tàbí ohun tí a fi awọ ṣe bá di aláwọ̀ ewé tàbí kí ó pupa, ààrùn ẹ̀tẹ̀ ni èyí, kí a sì fihàn àlùfáà.

Leviticus 13:49 (UKJV) And if the plague be greenish or reddish in the garment, or in the skin, either in the warp, or in the woof, or in any thing of skin; it is a plague of leprosy, and shall be showed unto the priest:

47“Bí ààrùn ẹ̀tẹ̀ bá ba aṣọ kan jẹ́ yálà aṣọ onírun àgùntàn tàbí aṣọ funfun.

48Ìbá à ṣe títa tàbí híhun tí ó jẹ́ aṣọ funfun tàbí irun àgùntàn, bóyá àwọ̀ tàbí ohun tí a fi àwọ̀ ṣe.

49Bí ààrùn náà bá ṣe bí ọbẹdo tàbí bi pupa lára aṣọ, ìbá à ṣe awọ, ìbá à ṣe ní ti aṣọ títa, ìbá à ṣe ní ti aṣọ híhun tàbí ohun tí a fi awọ ṣe bá di aláwọ̀ ewé tàbí kí ó pupa, ààrùn ẹ̀tẹ̀ ni èyí, kí a sì fihàn àlùfáà.

50Àlùfáà yóò yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, yóò sì pa gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà ti ràn mọ́ fún ọjọ́ méje.

51Ní ọjọ́ keje kí ó yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ràn ká ara aṣọ tàbí irun àgùntàn, aṣọ híhun tàbí awọ, bí ó ti wù kí ó wúlò tó, ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí jẹ́, irú ohun bẹ́ẹ̀ kò mọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.