Luku 1

Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.

Luke 1:47 (UKJV) And my spirit has rejoiced in God my Saviour.

45Alábùkún fún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́, nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”

46Maria sì dáhùn, ó ní: “Ọkàn mi yin Olúwa lógo.

47Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.

48Nítorí tí ó síjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀. Sá wò ó, láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.

49Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi; Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.