16Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn: Simoni (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Peteru),
17Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí “àwọn ọmọ àrá”).
18Àti Anderu, Filipi, Bartolomeu, Matiu, Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, Taddeu, Simoni tí ń jẹ́ Sealoti
19àti Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.
20Nígbà náà ni Jesu sì wọ inú ilé kan, àwọn èrò sì tún kórajọ, tó bẹ́ẹ̀ tí Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò rí ààyè láti jẹun.