12Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ láti Asiria àti ìlú ńlá Ejibiti àní láti Ejibiti dé Eufurate láti Òkun dé Òkun àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.
13Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé inú rẹ̀, nítorí èso ìwà wọn.
14Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ, èyí tí ó ń dágbé nínú igbó ní àárín Karmeli. Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi bí ọjọ́ ìgbàanì.
15“Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Ejibiti wá, ni èmi yóò fi ohun ìyanu hàn án.”
16Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n, nínú gbogbo agbára wọn. Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn, etí wọn yóò sì di.