7Nínú àwọn ìran Benjamini: Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Joẹdi, ọmọ Pedaiah, ọmọ Kolaiah, ọmọ Maaseiah, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaiah,
8àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Gabbai àti Sallai jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ (928) ọkùnrin.
9Joẹli ọmọ Sikri ni olórí òṣìṣẹ́ wọn, Juda ọmọ Hasenuah sì ni olórí agbègbè kejì ní ìlú náà.
10Nínú àwọn àlùfáà: Jedaiah; ọmọ Joiaribu; Jakini;
11Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, àwọn ni olórí tó ń bojútó ilé Ọlọ́run,