Numeri 13

Mose sì rán wọn jáde láti aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli.

Numbers 13:3 (UKJV) And Moses by the commandment of the LORD sent them from the wilderness of Paran: all those men were heads of the children of Israel.

1Olúwa sọ fún Mose pé,

2“Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kenaani wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Israẹli. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.”

3Mose sì rán wọn jáde láti aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli.

4Orúkọ wọn nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakkuri;

5láti inú ẹ̀yà Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori;

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.