15àti ní ìṣàn odò tí ó darí sí ibùjókòó Ari tí ó sì fi ara ti ìpínlẹ̀ Moabu.”
16Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Beeri, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mose, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”
17Nígbà náà ni Israẹli kọ orin yìí pé, “Sun jáde, ìwọ kànga! Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀,
18nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́, nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ; tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.” Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana,
19láti Mattana lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli lọ sí Bamoti,