Numeri 22

Balaki sì sọ fún Balaamu pé, “Ǹjẹ́ èmi kò a ránṣẹ́ kánjúkánjú sí ọ? Kí ló dé tí ìwọ kò fi wá sí ọ̀dọ̀ mi? Ṣé èmi kò tó láti sọ ọ́ di ẹni ńlá?”

Numbers 22:37 (UKJV) And Balak said unto Balaam, Did I not earnestly send unto you to call you? wherefore came you not unto me? am I not able indeed to promote you to honour?

35Angẹli Olúwa sọ fún Balaamu pé, “Lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin náà, ṣùgbọ́n nǹkan tí mo sọ fún ọ nìkan ni kí o sọ.” Nígbà náà Balaamu lọ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Balaki.

36Nígbà tí Balaki gbọ́ pé Balaamu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Moabu tí ó wà ní agbègbè Arnoni, ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ̀.

37Balaki sì sọ fún Balaamu pé, “Ǹjẹ́ èmi kò a ránṣẹ́ kánjúkánjú sí ọ? Kí ló dé tí ìwọ kò fi wá sí ọ̀dọ̀ mi? Ṣé èmi kò tó láti sọ ọ́ di ẹni ńlá?”

38Balaamu sì wí fún Balaki pé, “Kíyèsi, èmi tọ̀ ọ́ wá, èmi kò ha ní agbára kan nísinsin yìí rárá láti wí ohun kan? Mo gbọdọ̀ sọ nǹkan tí Ọlọ́run fi sí mi lẹ́nu.”

39Nígbà náà Balaamu lọ pẹ̀lú Balaki sí Kiriati-Hosotia.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.