39Nígbà náà Balaamu lọ pẹ̀lú Balaki sí Kiriati-Hosotia.
40Balaki rú ẹbọ akọ màlúù pẹ̀lú àgùntàn, ó sì fún Balaamu ní díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.
41Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Balaki gbé Balaamu lọ sí Bamoti Baali, láti ibẹ̀ ló ti rí apá kan àwọn ènìyàn.