Numeri 24

“Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu, àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli!

Numbers 24:5 (UKJV) How goodly are your tents, O Jacob, and your tabernacles, O Israel!

3ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, “Àsọtẹ́lẹ̀ tí Balaamu ọmọ Beori, àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere,

4àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ là kedere.

5“Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu, àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli!

6“Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde, gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá, gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn, gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.

7Omi yóò sàn láti inú garawa: èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. “Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ; ìjọba wọn yóò di gbígbéga.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.