14àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;
15ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,
16akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,
17akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Wọ̀nyí ni ọrẹ Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.
18Ní ọjọ́ kejì ni Netaneli ọmọ Suari olórí àwọn ọmọ Isakari mú ọrẹ tirẹ̀ wá.