19Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau, àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní. Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria; Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.
20Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaani yóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati; àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefaredi yóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní.
21Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wá láti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau. Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.