1Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.
2Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́, láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.
3Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo, àti ìdájọ́, àti àìṣègbè;
4láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀, ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.
5Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.