14Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idà àwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹ láti jẹ àwọn tálákà run kúrò ní ilẹ̀ ayé àwọn aláìní kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
15“Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì. ‘Mú wá! Mú wá!’ ní wọn ń ké. “Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé, mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!’:
16Ibojì, inú tí ó yàgàn, ilẹ̀ tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé, àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’
17“Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀, tí ó kẹ́gàn ìgbọ́ràn sí ìyá, ẹyẹ ìwò ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́, igún yóò mú un jẹ.
18“Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi, mẹ́rin tí kò yé mi,