21“Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrì lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.
22Ìránṣẹ́ tí ó di ọba aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,
23obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọ ìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.
24“Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi.
25Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá, síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò.