11Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora, nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán.
12Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!
13N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu, tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
14Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
15Mu omi láti inú kànga tìrẹ, omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ.