18Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà, ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
22“Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;