Saamu 10

O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí. Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”

Psalm 10:6 (UKJV) He has said in his heart, I shall not be moved: for I shall never be in adversity.

4Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀; kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀.

5Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo; òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i; òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.

6O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí. Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”

7Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ; wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.

8Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò. Ò gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀. Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.