9O bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ; o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù.
10O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n.
11Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.
12Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́ wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.
13Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ.