12Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́ wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.
13Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ.
14Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò.
15Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.
16Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.