24Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.
25Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.
26Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,
27láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.
28Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori, wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà,