Saamu 106

Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́? Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.

Psalm 106:3 (UKJV) Blessed are they that keep judgment, and he that does righteousness at all times.

1Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

2Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa, ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?

3Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́? Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.

4Rántí mi, Olúwa, nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn, wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,

5kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn, kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn, ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.