31A sì ka èyí sí òdodo fún un àti fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀
32Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú, ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.
33Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹ̀mí Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.
34Wọn kò pa àwọn ènìyàn run gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún wọn,
35Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn.