33Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹ̀mí Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.
34Wọn kò pa àwọn ènìyàn run gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún wọn,
35Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn.
36Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.
37Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.