2Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa, nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
3Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun; ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.
4Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀; àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.
5Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi, àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.
6Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú, ní ọ̀run àti ní ayé, ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.