Saamu 22

Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ; ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó.

Psalm 22:3 (UKJV) But you are holy, O you that inhabit the praises of Israel.

1Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀? Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe ìkérora mi?

2Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn: àti ní òru èmi kò dákẹ́.

3Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ; ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó.

4Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ; wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.

5Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.