Saamu 25

Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́; nítorí pé mo dúró tì ọ́.

Psalm 25:21 (UKJV) Let integrity and uprightness preserve me; for I wait on you.

19Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi, tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.

20Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀; má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú, nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.

21Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́; nítorí pé mo dúró tì ọ́.

22Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run, nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.