2Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ; má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
3Ẹni tí ó dúró tì ọ́ ojú kì yóò tì í, àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí ni kí ojú kí ó tì.
4Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa, kọ mi ní ipa tìrẹ;
5ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi; ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
6Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá, torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́.