Saamu 28

Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti, pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.

Psalm 28:3 (UKJV) Draw me not away with the wicked, and with the workers of iniquity, which speak peace to their neighbours, but mischief is in their hearts.

1Ìwọ Olúwa, mo ké pe àpáta mi. Má ṣe kọ etí dídi sí mi. Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi, èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.

2Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú, bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè sí Ibi Mímọ́ rẹ Jùlọ.

3Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti, pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.

4San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn àti fún iṣẹ́ ibi wọn; gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn; kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.

5Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ òun ó rún wọn wọlẹ̀ kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.