Saamu 31

Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára; gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

Psalm 31:16 (UKJV) Make your face to shine upon your servant: save me for your mercies' sake.

14Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa; mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”

15Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi àti àwọn onínúnibíni.

16Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára; gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

17Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa; nítorí pé mo ké pè ọ́; jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú; jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.

18Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́, pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn, wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.