Saamu 31

Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa; mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”

Psalm 31:14 (UKJV) But I trusted in you, O LORD: I said, You are my God.

12Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú; èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.

13Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká; tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi láti gba ẹ̀mí mi.

14Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa; mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”

15Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi àti àwọn onínúnibíni.

16Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára; gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.