24Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi!
25Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!” Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.”
26Kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọn kí ó sì dààmú pọ̀, àní àwọn tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi.
27Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú; kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni Olúwa, sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”
28Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ, àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.