Saamu 35

Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi, ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.

Psalm 35:7 (UKJV) For without cause have they hid for me their net in a pit, which without cause they have dug for my soul.

5Jẹ́ kí wọn dàbí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́, kí angẹli Olúwa kí ó máa lé wọn kiri.

6Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́, kí angẹli Olúwa kí ó máa lépa wọn!

7Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi, ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.

8Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì. Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀; kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.

9Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa, àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.