12Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi; àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun, wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.
13Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀; àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
14Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀, àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
15Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè; ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
16Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí; nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”