18Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi; àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
20Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi àwọn ni ọ̀tá mi nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.
21Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa! Ọlọ́run mi, má ṣe jìnnà sí mi.
22Yára láti ràn mí lọ́wọ́, Olúwa, Olùgbàlà mi.