Saamu 44

Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?

Psalm 44:21 (UKJV) Shall not God search this out? for he knows the secrets of the heart.

19Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá, ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú, tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.

21Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?

22Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́ a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

23Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn? Dìde fúnra rẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.