Saamu 44

Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.

Psalm 44:4 (UKJV) You are my King, O God: command deliverances for Jacob.

2Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde, Ìwọ sì gbin àwọn baba wa; ìwọ run àwọn ènìyàn náà Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.

3Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ; àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.

4Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.

5Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú; nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀,

6èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi, idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.