7Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run.
8Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
9ní ti kí ó máa wà títí ayé láìrí isà òkú.
10Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú, bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé, ibùgbé wọn láti ìrandíran, wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.