9Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run; ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
10Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
11Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀, púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
12“Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ; obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
13Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran, nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà, àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”