Saamu 69

Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn; kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

Psalm 69:24 (UKJV) Pour out yours indignation upon them, and let your wrathful anger take hold of them.

22Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

23Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran, kí ẹ̀yin wọn di títẹ̀ títí láé.

24Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn; kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

25Kí ibùjókòó wọn di ahoro; kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.

26Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù, àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.